Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16:27-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí sí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ara túbú ti sá lọ.

28. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má se pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn yìí!”

29. Nígbà tí ó sì beere iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà.

30. Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”

31. Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jéṣù Kírísítì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16