Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì wá sí Dábè àti Lísírà: sí kíyèṣi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Tìmótíù, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Gíríkì ní baba rẹ̀.

2. Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lísírà àti Ìkóníónì.

3. Òun ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbégbé wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Gíríkì ni baba rẹ̀.

4. Bí wọn sì ti ń la àwọn Ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerúsálémù, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́.

5. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹmúlẹ̀ ní ìgbágbọ́, wọn ṣí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojumọ́.

6. Wọ́n sì la agbégbé Fírígíà já, àti Gálátíà, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti ṣọ ọ̀rọ̀ náà ni Éṣíà.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16