Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Féníkè àti Samaríà kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin.

4. Nígbà tí wọn sì dé Jerúsálémù, àti àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.

5. Ṣùgbọ́n àwọn kan ti ẹ̀yà àwọn Farisí tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mósè mọ́.”

6. Àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí.

7. Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Pétérù dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́.

8. Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olúmọ-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa.

9. Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárin àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́.

10. Ǹjẹ́ nítorí náà è é ṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù?

11. Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jésù àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”

12. Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi ẹ̀rí sí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́-àṣẹ àti iṣẹ́-àmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn aláìkọlà.

13. Lẹ̀yìn tí wọn sì dákẹ́, Jákọ́bù dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi:

14. Símóòní ti róyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojúwo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15