Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. ÀWỌN ọkùnrin kan tí Jùdíà sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arakùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mósè, ẹ̀yin kí yóò lè là.”

2. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánabà ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú wọn, wọ́n yan Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àti àwọn mìíràn nínú àpósítélì kí wọn gòkè lọ sí Jerúsálémù, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí.

3. Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Féníkè àti Samaríà kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin.

4. Nígbà tí wọn sì dé Jerúsálémù, àti àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.

5. Ṣùgbọ́n àwọn kan ti ẹ̀yà àwọn Farisí tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mósè mọ́.”

6. Àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí.

7. Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Pétérù dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́.

8. Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olúmọ-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa.

9. Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárin àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15