Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 14:13-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Àlùfáà Júpítérì, ẹni ti ilé òrìsà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn, ó sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu-ibode láti rúbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn àpósítélì wọ̀nyí.

14. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn àpósítélì Bánábà àti Pọ́ọ̀lù gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé:

15. “Ará, è é ṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìyìn rere fún yín, kí ẹ̀yin baà lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, àti òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.

16. Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà ti wọn.

17. Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.”

18. Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rúbọ bọ wọ́n.

19. Àwọn Júù kan sì ti Áńtíókù àti Ìkóníónì wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kan padà, wọ́n sì sọ Pọ́ọ̀lù ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣèbí ó kú.

20. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Bánábà lọ sí Dábè.

21. Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìyìn rere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lísírà, àti Ikóníónì, àti Áńtíókù,

22. wọn sì ń mú àwọn ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró ní ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ̀njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run.

23. Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi à wọ́n lé ẹni gbàgbọ́ Olúwa lọ́wọ́.

24. Nígbà tí wọn sí la Pásídíà já, wọ́n wá sí Páḿfílíà.

25. Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Págà, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ataláyà:

26. Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Ańtíókù ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí

27. Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà.

28. Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 14