Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:19-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kénááni, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.

20. Gbogbo èyí sì sẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450) ọdún. Lẹ̀yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídájọ̀ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samueli wòlíì.

21. Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì bèèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, ọkùnrin kan nínú ẹ̀ya Bẹ́ńjámínì, fún ogójì ọdún.

22. Nígbà ti ó sì mú Ṣọ́ọ̀lù kúrò, ó gbé Dáfídì dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dáfídì ọmọ Jésè ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’

23. “Láti inú irú ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jésù Olugbàlà dìde fún Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

24. Ṣáájú wíwa Jésù ni Jòhánù ti wàásù bamítísímù ìrónúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Isírẹ́lì.

25. Bí Jòhánù sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, ‘Ta ni ẹ̀yin ṣèbí èmi jẹ́? Èmi kì í ṣe òun. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsí í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú.’

26. “Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Ábúráhámù, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí.

27. Nítorí àwọn tí ń gbé Jerúsálémù, àti àwọn olórí wọn, nítorí ti wọn kò mọ̀ Jésù, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi.

28. Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pílátù láti pá a.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13