Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 1:14-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Màríà ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.

15. Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Pétérù sí díde dúró láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn gbogbo nínú ìjọ jẹ́ ọgọ́fà)

16. ó w í pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé-Mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dáfídì nípa Júdásì, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jésù:

17. nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń se tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́-ìránṣẹ́ yìí.”

18. (Júdásì fi èrè àìsòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì subú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ifun rẹ̀ sì tú jáde.

19. Ó si di mímọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerúsálémù; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Ákélídámà ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ́.)

20. Pétérù sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ pé nínú Ìwé Ṣáàmù pé,“ ‘Jẹ́ ki ibùjókòó rẹ̀ di ahoro,kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’àti,“ ‘ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’

21. Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọn tí wọn ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jésù Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrin wa.

22. Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitíìsì Jòhánù títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”

23. Wọn sì yan àwọn méjì, Jósẹ́fù tí a ń pè ní Básábà, (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Júsítúsì) àti Màtíà.

24. Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn

25. kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́-ìránṣẹ́ àpósítélì yìí, èyí tí Júdásì kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀.”

26. Wọ́n sì dìbò fún wọn; ibò sí mú Mátíà; a sì kà á mọ́ àwọn àpósitélì mọ́kànlá.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 1