Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 2:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí Pétérù wá sí Ańtíókù, mo ta kò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ ẹni tí à bá báwí.

12. Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fà sẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà.

13. Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lati jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Bánábà lọnà.

14. Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédéé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìyìn rere, mo wí fún Pétérù níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn aláìkọlà, è é ṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn aláìkọlà láti máa rìn bí àwọn Júù?

15. “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’

16. Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, àní àwa pẹ̀lú gbà Jésù Kírísítì gbọ́, kí a báa lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kírísítì, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

17. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kírísítì, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ́lú jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kírísítì ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì!

18. Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fí ara mi hàn bí arúfin.

19. Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láàyè sí Ọlọ́run.

20. A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kírísítì, èmí kò sì wà láàyè mó, ṣùgbọ́n Kírísítì ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láàyè nínú ara, mo wà láàyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkararẹ̀ fún mi.

Ka pipe ipin Gálátíà 2