Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 1:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jésù Kírísítì àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú.

2. Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi,Sí àwọn ìjọ ní Gálátíà:

3. Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa,

4. ẹni tí ó fí òun tìkararẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,

5. ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

6. Ẹnu yà mi nítorí tí pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kírísítì, sí ìyìn rere mìíràn:

7. èyí tí kì í ṣe ìyìn rere rárá. Ìdánilójú wà pé àwọn kan wà tí wọ́n ń sì yín lọ́nà, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìn rere Kírísítì padà.

8. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí ańgẹ́lì kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìyìn rere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!

9. Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsinyìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìyìn rere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!

10. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kírísítì.

11. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìyìn rere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn.

12. N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì.

13. Nítorí ẹ̀yin ti gbúrò ìwà-ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́:

14. Mo sì ta ọ̀pọlọ́pọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrin àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọpọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi.

Ka pipe ipin Gálátíà 1