Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 4:5-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìtẹ̀bọmi kan.

6. Ọlọ́run kan ati Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó se olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú gbogbo.

7. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kírísítì.

8. Nitorí náà a wí pé:“Nígbà tí ó gókè lọ sí ibi gíga,ó di ìgbékùn ni ìgbékùn,ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”

9. (Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ” Kín ni ó jẹ́, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìhà ìṣàlẹ̀ ilẹ̀?

10. Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.)

11. Ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí àpósítélì; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí ajínyìnrere, àti àwọn mìíràn bí Olùṣọ́ àgàntàn àti olùkọ́ni.

12. Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ fun iṣẹ́ ìráńṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kírísítì.

13. Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kírísítì.

14. Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni sìnà;

15. Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kírísítì.

16. Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípaṣẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkárárẹ̀ dìde nínú ìfẹ́.

17. Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn.

18. Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, àwọn tí ó sì di àjèjì sí ìwà-bí-Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí lílè ọkàn wọn.

19. Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọ́ra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo.

20. Ṣùgbọ́n a kò fi Kírísítì kọ́ yín bẹ́ẹ̀.

21. Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí otítọ́ ti ń bẹ nínú Jésù.

22. Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ogbologbo ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ̀ bí ìfẹ́kúfẹ́ ẹ̀tàn;

23. Kí ẹ sì di titun ni ẹ̀mí inú yín;

Ka pipe ipin Éfésù 4