Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 2:10-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kírísítì Jésù fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèṣè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.

11. Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ aláìkọlà nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní Akọlà ti a fi ọwọ́ ṣe ni ara ń pè ní Aláìkọlà.

12. ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kírísítì, ẹ jẹ́ àjèjì sí àǹfàní àwọn ọlọ̀tọ̀ Ísírẹ́lì, àti àlejò sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé:

13. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kírísítì Jésù ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kírísítì.

14. Nítorí oun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórira èyí tí ń bẹ láàrin yín.

15. Nípa pípa àṣẹ, àwọn òfin àti ìlànà gbogbo rẹ̀ nínú ara rẹ̀. Àfojúsùn rẹ̀ i kí ó le dá ọkùnrin tuntun kan nínú ara rẹ̀ nínú àwọn méjèèjì, kí àlááfíà kí ó lè wà nípa èyí.

16. àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìsòtá náà run.

17. Ó sì ti wá ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlááfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòòsí.

18. Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.

19. Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àtìpó mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ara ilé Ọlọ́run;

20. a sì ń gbé yín ró lórí ìpilẹ̀ àwọn àpostélì, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jésù Kírísítì fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé;

21. Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ sọ̀kan tí ó sì ń dàgbà sókè láti di tẹ́ḿpìlì mímọ́ kan nínú Olúwa:

22. Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pọ̀ pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.

Ka pipe ipin Éfésù 2