orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìsọdààyè nínú Kírísítì

1. Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín,

2. nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí àní bí ipá ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni isinsìn yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.

3. Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú.

4. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa,

5. nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kírísítì oore ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là.

6. Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kírísítì, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kírísítì Jésù.

7. Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣehun rẹ̀ sì wà nínú Kírísítì Jésù.

8. Nítorí oore ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́: àti èyí yìí kì í ṣe ti láti ọ́dọ̀ ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni:

9. Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.

10. Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kírísítì Jésù fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèṣè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.

Ọ̀kan Nínú Kírísítì

11. Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ aláìkọlà nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní Akọlà ti a fi ọwọ́ ṣe ni ara ń pè ní Aláìkọlà.

12. ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kírísítì, ẹ jẹ́ àjèjì sí àǹfàní àwọn ọlọ̀tọ̀ Ísírẹ́lì, àti àlejò sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé:

13. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kírísítì Jésù ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kírísítì.

14. Nítorí oun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórira èyí tí ń bẹ láàrin yín.

15. Nípa pípa àṣẹ, àwọn òfin àti ìlànà gbogbo rẹ̀ nínú ara rẹ̀. Àfojúsùn rẹ̀ i kí ó le dá ọkùnrin tuntun kan nínú ara rẹ̀ nínú àwọn méjèèjì, kí àlááfíà kí ó lè wà nípa èyí.

16. àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìsòtá náà run.

17. Ó sì ti wá ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlááfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòòsí.

18. Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.

19. Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àtìpó mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ara ilé Ọlọ́run;

20. a sì ń gbé yín ró lórí ìpilẹ̀ àwọn àpostélì, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jésù Kírísítì fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé;

21. Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ sọ̀kan tí ó sì ń dàgbà sókè láti di tẹ́ḿpìlì mímọ́ kan nínú Olúwa:

22. Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pọ̀ pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.