Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 8:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lìdá lẹ̀yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn,èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn,èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn,wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.

11. Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀,tàbi olukulùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘mọ Olúwa,’Nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí,láti kékere dé àgbà.

12. Nítorí pé èmi ó ṣáànu fún àìṣódodo wọn,àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àiṣedeede wọn lèmí ki yóò sì rántí mọ́.”

13. Ní èyí tí ó wí pé, Májẹ̀mu títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 8