14. “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.”
15. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ̀yìn ìgbà tí Ábúráhámù fi súúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.
16. Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀ṣẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀.
17. Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidgidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrin wọn.
18. Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú sinsin:
19. Èyí tí àwa ní bi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ̀yìn aṣọ ìkélé;
20. Níbi tí Jésù, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ Olórí àlùfáà títí láé nípasẹ̀ Melekisédékì.