Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 5:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀.

2. Ẹni tí ó lè bá àwọn aláìmòye àti àwọn tí ó ti yapa kẹ̀dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú.

3. Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń se fún ara rẹ̀ náà.

4. Ko sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò se ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Árọ́nì.

5. Bẹ́ẹ̀ ni Kírísítì pẹ̀lú kò si ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé,“Ìwọ ni ọmọ mi,lónìn-ín ni mo bi ọ.”

6. Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibò mìíràn pé,“Ìwọ ni àlùfáà títí láéní ipasẹ̀ Melikisédékì.”

7. Ní ìgbà ọjọ́ Jésù nínú ayé, ó fi ẹkún rara àti omije gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀.

8. Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ gbọ́ràn nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀;

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 5