Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 4:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí àti wọ inú ìsinmi rẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má baà dà bí ẹni pé ó tí kùnà rẹ̀.

2. Nítorí tí àwá gbọ́ ìwàásù ìyìn rere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní ire, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ.

3. Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí,“Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpilẹ̀ ayé.

4. Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ kéje bayìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.”

5. Àti níhìn yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”

6. Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a tí wàásù ìyìn rere náà fún ní ìṣáajú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn:

7. Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dáfídì pé, “Lònìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí niṣáájú,“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”

8. Nítorí, ìbá ṣe pé Jóṣúà tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ̀yìn náà,

9. nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

10. Nítorí pé ẹni tí ó ba bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀, òun pẹ̀lú sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀.

11. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má baà ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 4