Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 3:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n Kírísítì jẹ́ olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwá jẹ́, bí àwá bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.

7. Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mi Mímọ́ tí wí:“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

8. Ẹ má ṣe sé ọ̀kan yin le,bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní ihà:

9. Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.

10. Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn sìnà ní ọkàn wọn;wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’

11. Bí mo tí búra ní ìbínú mi,‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”

12. Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.

13. Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjù ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnìkẹni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.

14. Nítorí àwá di alábàápín pẹ̀lú Kírísítì, bí àwá bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin;

15. Nígbà tí a ń wí pé:“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má se ọ̀kan yin le,bí ìgbà ìmúnibínú.”

16. Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Éjíbítì ní abẹ́ àkóso Mósè?

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 3