Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 2:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ àmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.

5. Nítórí pé, kì í ṣe abẹ́ ìsàkóso àwọn ańgẹ́lì ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí.

6. Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé:“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?

7. Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ańgẹ́lì lọ;ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ:

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 2