Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 13:10-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ.

11. Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si ibi mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ̀yìn ibùdó.

12. Nítorí náà Jésù pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ̀yìn ìbodè.

13. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ̀yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀.

14. Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níyin, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.

15. Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.

16. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín funni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ

17. Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríbà fún wọ́n: Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀sọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìsírò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín.

18. Ẹ máa gbàdúrà fún wa: Nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo.

19. Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà.

20. Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùsọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu ayérayé, àní Olúwa wa Jésù.

21. Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jésù Kírísítì; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín

22. Èmi sì ń bẹ̀ yín ará, ẹ gbà ọ̀rọ̀ ìyànjú mi; nítorí ìwé kukuru ni mo kọ sí yín.

23. Ẹ mọ pé a sá Timótéù arákùnrin wa sílẹ̀; bí ó ba tètè dé, èmí pẹ̀lú rẹ̀ yóò rí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.

24. Ẹ ki gbogbo àwọn tí ń ṣe olórí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Àwọn tí o ti Ítalì wá ki yín.

25. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 13