Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 10:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí òfin, bí o ti ní òjìjì àwọn ohun rere ti ń bẹ̀ tí kì í ṣe àwòrán tóòtọ́ fún rere nǹkan náà, kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbàgbogbo lọdọ́ọ̀dún mu àwọn tí ń wá sibẹ̀ di pípé.

2. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a ba ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo.

3. Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìranti ẹ̀ṣẹ̀ lọdọ́ọ̀dún.

4. Nítorí ko ṣeeṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.

5. Nítorí náà nígbà tí Kísítì wá sí ayé, ó wí pé,“Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi;

6. Ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ niìwọ kò ní inú dídùn sí.

7. Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsí i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọọ́ nípa ti èmi)mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”

8. Nígbà tí o wí ni ìṣáajú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọ̀rẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).

9. Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsí i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” O mu ti ìṣáaju kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀.

10. Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jésù Kírísítì fi ara rẹ̀ rú lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo.

11. Àti olukulùkù àlùfáà sì ń dúró lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ ìsìn, ó sì ń ṣe ẹbọ kan náà nígbàkúgbà, tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò láé:

12. Ṣùgbọ́n òun, lẹ̀yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jòkòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run;

13. Láti ìgbà náà, ó rétí títí a o fi àwọn ọ̀ta rẹ̀ ṣe àpótí itísẹ̀ rẹ̀.

14. Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 10