orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tímótíù 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọ̀rọ̀ Ìkínní

1. Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì ti Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.

2. Sí Tímótíù, Ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n:Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kírísítì Jésù Olúwa wa,

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú Láti Jẹ́ Onígbàgbọ́

3. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn funfun gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsinmi lọ́sàn-án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi.

4. Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀.

5. Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìlẹ́tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá-ńlá rẹ, àti nínú Yùníìsì ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó da mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú.

6. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi.

7. Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìṣẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro.

8. Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ̀rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábàápín nínú ìpọ́njú ìyìnrere nípa agbára Ọlọ́run,

9. ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà-mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa láti ìpìlẹ̀ ayérayé,

10. ṣùgbọ́n tí a fihàn níṣinṣinyìí nípa ìfarahàn Jésù Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípaṣẹ̀ ìyìnrere.

11. Fún ti ìyìnrere tí a yàn mi ṣe oníwàásù àti Àpósítélì àti olùkọ́.

12. Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí: nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.

13. Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kírísítì Jésù.

14. Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.

15. Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Ésíà ti fí mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Fígélíù àti Hámógénè gbé wà.

16. Kí Olúwa fi àánú fún ilé Ònésífórù; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú.

17. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Rómù, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi.

18. Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkararẹ sáà mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà rànmí lọ́wọ́ ni Éfésù.