orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tímótíù 3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àìwùwà Bí Ọlọ́run Ni Ọjọ́ Ìkẹ̀yìn.

1. Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé.

2. Nitori àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀-búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́.

3. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlè-dáríjí-ni, abanijẹ́, aláìlè-kó-rawọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere,

4. oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ.

5. Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwá-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

6. Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ fà kiri

7. Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́.

8. Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Jánésì àti Jámbérì ti kọ ojú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́.

9. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ ṣíwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú Pọ́ọ̀lù Sí Tìmótíù

10. Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́-ni sùúrù.

11. Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Ańtíókù, Ní Ìkóníónì àti ní Lísítírà; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn.

12. Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kírísítì Jésù yóò faradà inúnibíni

13. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ̀tàn yóò máa burú síwajú sí i, wọn ó máa tan-nijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ.

14. Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn.

15. Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ ìwé-Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ́ ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.

16. Gbogbo ìwé-Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo.

17. Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.