Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tẹsalóníkà 3:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín sọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kírísítì.

6. Ní orúkọ Jésù Kirisítì Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún-un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa.

7. Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa farawé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín.

8. Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣisẹ́ tọ̀sán-tòru kí a má baà di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn.

9. Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti bèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé.

10. Nítorí nígbà tí àwà wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún-un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”

11. A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrin yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlé-kiri.

12. Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ́ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jésù Kírísítì Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ.

13. Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere síṣe.

14. Bí ẹnikẹ́ni kò bá sì pa ofin wa nínú lẹ́tà yìí mọ́, ẹ ṣààmí sí ẹni náà. Ẹ má ṣe bá a kẹ́gbẹ́ kí ojú bà á le tì í.

15. Ṣíbẹ̀, ẹ má ṣe kà á sí ọ̀ta, ṣùgbọ́n ẹ máa kìlọ̀ fún-un gẹ́gẹ́ bí arakùnrin yín.

Ka pipe ipin 2 Tẹsalóníkà 3