Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tẹsalóníkà 3:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́.

3. Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi.

4. Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pa láṣẹ fún-un yín ni ẹ̀yin ń ṣe.

5. Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín sọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kírísítì.

Ka pipe ipin 2 Tẹsalóníkà 3