Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Pétérù 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Símónì Pétérù, ìránṣẹ́ àti Àpósítélì Jésù Kírísítì,Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye igbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jésù Kírísítì Olùgbàlà.

2. Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jésù Olúwa wá.

3. Agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí í ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀.

4. Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wá: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábàápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yín bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

Ka pipe ipin 2 Pétérù 1