Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 6:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí talákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.

11. Ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa payá sí yín.

12. A kò ni yín lára nítorí wa, ṣùgbọ́n a ni yín lára nítorí ìfẹ́ ọkàn ẹ̀yin fúnra yín.

13. Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, (èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé) ẹ̀yin náà, ẹ ṣí ọkàn yín payá pẹ̀lú.

14. Ẹ má ṣe fí àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí idápọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdápọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn?

15. Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kírísítì ní pẹ̀lú Bélíàlì? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?

16. Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé, “Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàárin wọn; èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”

17. “Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàárin wọn,kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,ni Olúwa wí.Ki ẹ má ṣe fi ọwọ kan ohun àìmọ́;Èmi ó sì gbà yín.”

18. “Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín,Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi!ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 6