Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù Àpósítélì Jésù Kírisítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Tímótíù arákùnrin wá, sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọ́ríńtí pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Ákáyà:

2. Oore-ọ̀fẹ́ si yín àti àlàáfíà làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jésù Kírísítì Olúwa.

3. Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo;

4. Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa lè máa pẹ̀lú tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

5. Nítorí pé bí ìjìyà Kírísítì ti sínú ayé wa,, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ pẹ̀lú nípa Kírísítì.

6. Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbi bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù làti mú yin ní irú ìfaradá ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́.

7. Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹyin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹyin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.

8. Ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Éṣíà, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́.

9. Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde:

10. Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé pé yóò sí máa gbà wá ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀,

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 1