orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ẹ̀kọ́ Sí Tímótíù

1. NÍṢÍNṢIN YÌÍ, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èsù.

2. Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkarawọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó.

3. Àwọn tí ń dá-ni-lẹ́kun láti gbéyàwó ti wọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́.

4. Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á.

5. Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà á sí mímọ́.

6. Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ iránṣẹ́ rere ti Kírísítì Jésù, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé.

7. Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.

8. Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwá-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti igbé-ayé ìṣinṣinyìí àti ti èyí tí ń bọ̀,

9. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ̀wọ́gbà gbogbo.

10. Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwá ní ìrèti nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.

11. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ̀ kí ó máa kọ́ni.

12. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan èrè rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwàhíhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́,

13. Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbani-níyànjú àti ìkọ́ni.

14. Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.

15. Má a fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọṣíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn.

16. Má a ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láiyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.