orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ẹ̀kọ́ Lórí Ìsìn

1. Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa sìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn.

2. Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àláfíà àti ìdákẹ́jẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́.

3. Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olúgbàlà wa;

4. Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.

5. Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrin Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kírísítì Jésù ọkùnrin náà.

6. Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ.

7. Nítorí èyí tí a yàn mi ṣe oníwàásù, Àpósítélì—òtítọ́ ni èmi ń sọ, èmi kò ṣèké olùkọ́ àwọn aláìkọlà nínú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.

8. Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn.

9. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsí ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun-dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye,

10. Bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.

11. Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́jẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́.

12. Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́jẹ́.

13. Nítorí Ádámù ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Éfà.

14. Ádámù kọ́ ni a tàn jẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀.

15. Ṣùgbọ́n a ó gbà àwọn obìnrin là nípa ìbímọ wọn, bí wọ́n bá dúró nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìwà-mímọ́ pẹ̀lú ìwà àìrékọjá.