Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 1:3-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Bí mo se rọ̀yín nígbàtí mò ń lọ sí Makedóníà, ẹ dúró ní Éfésù, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́

4. kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn-asán, àti ìtàn-ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́.

5. Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn.

6. Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápákan sí ọ̀rọ̀ asán.

7. Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.

8. Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára.

9. Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá àti àwọn apànìyàn,

10. fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.

11. Gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.

12. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹni tí ó fún mi ní agbára, àní Kírísítì Jésù Olúwa wa, nítorí tí ó kà mí sí olóòótọ́ ní yíyànmí sí iṣẹ́ rẹ̀;

13. Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn: ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́.

14. Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.

15. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jésù Kírísítì wá sí ayé láti gba ẹlẹ́sẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ.

Ka pipe ipin 1 Tímótíù 1