orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tẹsalóníkà 5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsìnyìí, ará, a kò nílò láti kọ ìwé sí i yín mọ́ nípa àkókò àti ìgbà,

2. nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wàá bí olè lóru.

3. Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àláfíà àti àbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí rí ibi ààbò láti sá sí.

4. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè.

5. Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan. Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́.

6. Nítorí náà, ẹ kíyèsára yín kí ẹ má ṣe sùn bí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ máa sọ́nà kí ẹ sì máa pa ara yín mọ́.

7. Nítorí àwọn tí owọ́n ń sùn, a máa sùn ní òru, àwọn ẹni tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru.

8. Ṣùgbọ́ń àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí awo igbaaya ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí asìborí.

9. Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jésù Kírísítì.

10. Jésù kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.

11. Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe.

Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn

12. Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrin yín tí wọn ń kìlọ̀ fún jẹ́ olórí fún yín nínú Olúwa.

13. Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ sì máa wà ni àlàáfíà láàrin ara yín.

14. Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrin yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ̀pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.

15. Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ maa lépa èyí tíi ṣe rere láàrin ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.

16. Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo

17. Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo

18. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kírísítì Jésù nítòótọ́.

19. Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́.

20. Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń ìsọtẹ́lẹ̀.

21. Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú.

22. Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi.

23. Kí Ọlọ́run àlàáfíà pàápàá wẹ̀ yín mọ́, kí ó sì yà yín sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́, títí di ìgbà wíwá Jésù Kírísítì Olúwa wa.

24. Olótítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.

25. Ẹ̀yin ará, ẹ gbàdúrà fún wa.

26. Ẹ gbà ara yín ní ọwọ́ ní orúkọ mi pẹ̀lú ọkàn funfun.

27. Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́ta yìí fún gbogbo àwọn ará.

28. Ki oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín. Àmín.