orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tẹsalóníkà 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Iṣẹ́ Pọ́ọ̀lù Ní Ìjọ Tẹsalóníkà

1. Ẹ̀yin pàápàá mọ̀, ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán.

2. Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Fílípì bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìyìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle.

3. Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í se ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè.

4. Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í se bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò se Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò.

5. A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa.

6. A kò bèèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí àpósítélì Kírísítì a ò bá ti di àjàgà fún un yín.

7. Ṣùgbọ́n àwa se pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrin yín tí a sì se ìtọ́jú yín gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

8. A fẹ́ràn yín púpọ̀, èyí ló mu kí ó ṣe é ṣe fún wa láti pín ìyìnrere náà fún yín pẹ̀lú ìgbésí ayé àwa pàápàá.

9. Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn-án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnìkẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín.

10. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrin ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

11. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀

12. ìyànjú, ìtùnnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkararẹ̀.

13. Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

14. Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́se àwọn ìjọ tí o wà ní Jùdíà jẹ. Bí a ti gbógun tì wọ́n, láti ọwọ́ àwọn ará ìlú wọn (àwọn Júù), bẹ́ẹ̀ ni a gbógun ti ẹ̀yin pàápàá láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù,

15. àwọn tí wọ́n pa Jésù Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn

16. nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrin àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀sẹ̀ wọn ń di púpọ̀ síi lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.

Pọ́ọ̀lù Ń Fẹ́ Láti Rí Àwọn Ìjọ Tẹsálóníkà.

17. Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín.

18. Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n Èṣù ú dè wá lọ́nà.

19. Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó sògo níwájú Jésù Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ ní?

20. Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa.