Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tẹsalóníkà 2:8-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. A fẹ́ràn yín púpọ̀, èyí ló mu kí ó ṣe é ṣe fún wa láti pín ìyìnrere náà fún yín pẹ̀lú ìgbésí ayé àwa pàápàá.

9. Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn-án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnìkẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín.

10. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrin ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

11. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀

12. ìyànjú, ìtùnnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkararẹ̀.

13. Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

14. Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́se àwọn ìjọ tí o wà ní Jùdíà jẹ. Bí a ti gbógun tì wọ́n, láti ọwọ́ àwọn ará ìlú wọn (àwọn Júù), bẹ́ẹ̀ ni a gbógun ti ẹ̀yin pàápàá láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù,

15. àwọn tí wọ́n pa Jésù Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn

16. nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrin àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀sẹ̀ wọn ń di púpọ̀ síi lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.

17. Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín.

18. Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n Èṣù ú dè wá lọ́nà.

19. Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó sògo níwájú Jésù Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ ní?

Ka pipe ipin 1 Tẹsalóníkà 2