Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Pétérù 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn.

2. Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín:

3. Kí ọ̀sọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀sọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀;

4. Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó farasìn ní ọkàn, nínú ọ̀sọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.

5. Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbaànì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi sẹ ara wọn lọ́sọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ tiwọn.

6. Gẹ́gẹ́ bí Sárà ti gbọ́ ti Ábúráhámù, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.

7. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi Òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.

8. Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀

9. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogun ìbùkún.

10. Nítorí,“Ẹni tí yóò bá fẹ ìyè,ti yóò sì rí ọjọ́ rere,kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:

Ka pipe ipin 1 Pétérù 3