Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Pétérù 1:17-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti ń képe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsáájú, ẹ máa lo ìgbà àtipó yin ni ìbẹ̀rù.

18. Níwọ̀nbí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín pàdà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.

19. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n ani ẹ̀jẹ̀ Kírísítì.

20. Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹ́yìn wọ̀nyí nítorí yín,

21. Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrétí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

22. Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnikejì yín gidigidi láti ọkàn wá.

23. Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láàyè tí ó sì dúró.

24. Nítorí pé,“Gbogbo ènìyàn dàbí kóríko,àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,

25. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìn rere tí a wàásù fún yín.

Ka pipe ipin 1 Pétérù 1