Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 9:21-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kírísítì), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin.

22. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi baà lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí.

23. Mo ṣe èyí láti lè rí ààyè láti wàásù ìyìn rere sí wọn àti fún ìbùkún tí èmi pàápàá ń rí gbà, nígbà tí mo bá rí i pé wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn Kírísítì.

24. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú rẹ̀ ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò kìn-ín-ní. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ baà le borí.

25. Láti borí nínú eré ìdíje, ẹ ní láti sẹ́ ara yín nínú ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó lè fá yín sẹ́yín nínú sísa gbogbo agbára yín. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run tí kò lè bàjẹ́ láéláé.

26. Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú àmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lóju. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà.

27. Ṣùgbọ́n èmi ń ń kó ara mi níjànu, mo sì n mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún áwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má se di ẹni ìtanú fún ẹ̀bùn náà.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 9