Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 8:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti iwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, lati jẹ oúnjẹ tí a fi rúbọ sí òrìsà?

11. Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kírísítì kú fún.

12. Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arakùnrin rẹ̀ tí ẹ sì n pá ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́sẹ̀ sí Kírísítì jùlọ.

13. Nítorí nàá, bí ẹran tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bá máa mú arákùnrin mi dẹ́ṣẹ̀, èmi kì yóò jẹ́ ẹran mọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè, nítorí n kò fẹ́ kí arákùnrin mi ṣubú sìnù ẹ̀ṣẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 8