Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 7:4-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀.

5. Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀sọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín gún ààwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pade, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí sátanì má baà dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn.

6. Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ.

7. Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi láìgbéyàwó, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bún tírẹ̀, ọ̀kan bí irú èyi àti èkejì bí irú òmíràn.

8. Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọn kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà.

9. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá lè mú ara dúró, kí wọn gbéyawó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyáwò jù láti ṣe ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ lọ.

10. Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.”

11. Ṣùgbọ́n tí ó bá kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó padà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ ti ó fi sílẹ̀ àti ọkùnrin pàápàá kò gbọdọ̀ fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀.

12. Mo fẹ́ fi àwọn àmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

13. Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

14. Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kírísítì gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kírísítì gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́.

15. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Onígbàgbọ́ ọkùnrin tàbí obìnrin náà kò sí lábẹ́ idè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlààfíà.

16. Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe mọ̀ pé ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ.

17. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù máa gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́ yín fún, àti nínú èyí tí Olúwa pè é sí. Ìlànà àti òfin mi fún gbogbo ìjọ ni èyi.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 7