Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 4:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìranṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọfẹ́ láti mọ Kírísítì tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.

2. Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú pẹ̀lú, ni kí ó jẹ́ olóòótọ́.

3. Èmí kò tilẹ̀ bìkítà pé, ẹ̀yin dá mi lẹ́jọ́, nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́.

4. Nítorí tí ẹ̀rí-ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdàjọ́ mi.

5. Nítorí náà, kí ẹ má ṣe se ìdájọ́ ohukóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó farasin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olukúlukù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ̀dọ́ Ọlọ́run.

6. Ẹ kíyèsí i pé, mo ti fi ara mi àti Àpólò ṣe àpẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe titorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”

7. Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, è é ti ṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?

8. Báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jọba pẹ̀lú yín!

9. Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa àpósítélì hàn ní ìkẹyin bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítori tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn ańgẹ́lì ati gbogbo ayé.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 4