Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 14:25-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi aṣiri ọkan rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sín Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrin yín!”

26. Ǹjẹ́ è é ha ti ṣe, ki ni ki àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin pé jọ pọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Sáàmù kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan, ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró.

27. Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbi bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀,

28. Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pá ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

29. Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ.

30. Bí a bá sì fí ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́.

31. Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ́kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú.

32. Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì.

33. Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà.Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ijọ ènìyàn mímọ́

34. Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ijọ: nítorí a kò fí fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ ki wọn wà lábẹ́ itẹríbá, bí ó ṣe rí ni gbogbo àpéjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

35. Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn bèèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.

36. Kí ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tabi ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá?

37. Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tabí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkán wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé ofin Olúwa ni wọ́n.

38. Ṣùgbọ́n bí ẹnikan bá fi ojú fo èyí dá, òun fún ra rẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.

39. Nítorí náà ará, ẹ máa fí ìtara ṣáfẹrí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dànílẹ́kún láti fi èdè fọ̀.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 14