Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 13:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti ańgẹ́lì, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí agogo lásàn ni tàbí bí i Síḿbálì olóhùn gooro.

2. Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ́, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè sí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan.

3. Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ̀, kò ní èrè kan fún mi.

4. Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ̀ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

5. Ìfẹ́ kì í huwa àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú.

6. Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìsòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo sí òtítọ́.

7. A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbógbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

8. Ìfẹ̀ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bún ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 13