Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Jòhánù 5:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jésù ni Kírísítì, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípaṣẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.

2. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.

3. Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira,

4. nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé: èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa.

5. Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ́ Ọlọ́run ni Jésù jẹ́?

6. Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jésù Kírísitì, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ̀rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí.

7. Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí.

8. Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan.

Ka pipe ipin 1 Jòhánù 5