Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 9:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu mi pẹ̀lú rẹ,Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.

12. Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ìrètí:àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́poméjì.

13. Èmi ó fa Júdà le bí mo ṣe fa ọrun mi le,mo sì fi Éfúráímù kún un,Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Ṣíónì,sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Gíríkì,mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.

14. Olúwa yóò sì fí arahàn ní orí wọnỌ̀kọ̀ rẹ̀ yóò tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Olúwa ọ̀gá-ògo yóò sì fọn ìpè,Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúṣù.

15. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n;wọn ó sì jẹ ni run,wọn ó sì tẹ òkúta kànnà-kànnà mọ́lẹ̀;wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì,wọn ó sì kún bí ọpọ́n,wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ.

16. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náàbí agbo ènìyàn rẹ̀:nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé,tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.

17. Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ ṣi tí pọ̀!Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá,ati ọtí-wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Sekaráyà 9