Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 9:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hádírákì,Dámásíkù ni yóò sì jẹ́ ibi ìṣinmi rẹ̀;nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn,àti lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

2. Àti Hámátì pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀Tírè àti Sídónì bí o tilẹ̀ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi.

3. Tírè sì mọ odi líle fún ara rẹ̀,ó sì kó fàdákà jọ bí èkuru,àti wúrà dáradára bí àfọ̀ ẹ̀rẹ̀ ìgboro.

4. Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ,yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú òkun,a ó sì fi iná jó o run.

5. Ásíkélónì yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù;Gásà pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káànú gidigidi,àti Ékírónì: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò sákì í.Gásà yóò pàdánu ọba rẹ̀,Ásíkélónì yóò sì di ahoro.

6. Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Ásídódì,Èmi yóò sì ge ìgbéraga àwọn Fílístínì kúrò.

7. Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀,àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrin eyín rẹ̀:ṣùgbọ́n àwọn tó sẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa,wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Júdà,àti Ékírónì ni yóò rí bí Jébúṣì.

8. Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi kánítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri,kò sí aninilára tí yóò là wọ́n já mọ́:nítorí ni ìṣinṣin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn.

Ka pipe ipin Sekaráyà 9