Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 8:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá, wí pé,

2. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńlá-ńlá ni mo jẹ fún Síónì, pẹ̀lú ìbínú ńlá-ńlá ni mo fi jowú fún un.”

3. Báyìí ni Olúwa wí: “Mo yípadà sí Síónì èmi ó sì gbé àárin Jérúsálẹ́mù: Nígbà náà ni a ó sì pé Jérúsálẹ́mù ni ìlú ńlá otítọ́; àti òkè-ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè-ńlá mímọ́.”

4. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jérúsálẹ́mù, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó.

5. Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdé-bìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”

6. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanú ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyánú ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

7. Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kiyesi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn.

8. Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárin Jérúsálẹ́mù: wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”

9. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹ́ḿpìlì.

10. Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olukuluku kọ aládùúgbò rẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n ní ìṣinṣinyìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

12. “Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀: àjàrà yóò ṣo èṣo rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

Ka pipe ipin Sekaráyà 8