Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 5:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?”Ó sì wí pé, “Èyí ni òṣùwọ̀n éfà tí ó jáde lọ.” Ó sì wí pé, “Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”

7. Sì kíyèsí i, a gbé talẹ́ńtì òjé sókè: obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárin òṣùwọ̀n éfà.

8. Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà-búburú.” Ó sì jù ú sí àárin òṣùwọ̀n éfà: ó sì ju òṣùwọ̀n òjé sí ẹnu rẹ̀.

9. Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, obìnrin méjì jáde wá, èfúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀: Wọ́n sì gbé òṣùwọ̀n éfà náà dé àárin méjì ayé àti ọ̀run.

10. Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òṣùwọ̀n éfà náà lọ.”

Ka pipe ipin Sekaráyà 5