Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mó si tún gbé ojú mi, sòkè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn-ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀.

2. Mo sí wí pé, “Níbo ni ìwọ ń lọ?”O sí wí fún mí pé, “Láti wọn Jérúsálẹ́mù, láti rí iyé ìbú rẹ̀, àti iyé gígùn rẹ̀.”

3. Sì kiyesí i, ańgẹ́li tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, ańgẹ́lì mìíràn si jáde lọ pade rẹ̀.

4. Ó si wí fún un pé, “Sáré, sọ fún ọdọmọkùnrin yìí wí pé, ‘A ó gbé inú Jérúsálẹ́mù bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun-ọ̀sìn inú rẹ̀.

5. Olúwa wí pé, Èmí ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrin rẹ̀.’

6. “Áà! Áà! Sá kúrò ni ilẹ̀ àriwá, ni Olúwa wí; nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín kákiri,” ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Sekaráyà 2