Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 1:4-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé: Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí: ‘Ẹ yípadà nísinsìnyìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí.

5. Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọn ha wà títí ayé?

6. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pà ni àṣẹ fún àwọn ìrànsẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín?“Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”

7. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sébátì, ní ọdún kejì Dáríúsì, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sekaráyà, ọmọ Berekáyà ọmọ Idò wòlíì wá, pé,

8. Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin púpa kan, òun sì dúró láàrin àwọn igi míritílì tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ si ni ẹ̀ṣin púpa, adíkálà, àti funfun gbé wà.

9. Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí Olúwa mi?”Ańgẹ́lì tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”

10. Ọkùnrin tí ó dúró láàrin àwọn igi míritílì sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”

11. Wọ́n si dá ańgẹ́lì Olúwa tí ó dúró láàrin àwọn igi mirtílì náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti ríi pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”

12. Nígbà náà ni ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jérúsálẹ́mù, àti fún àwọn ìlú ńlá Júdà, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?”

13. Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.

14. Ańgẹ́lì ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbé wí pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jówú fún Jérúsálẹ́mù àti fún Síónì.

15. Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí o gbé jẹ́ẹ: nítorí nígbà ti mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀ṣíwájú.’

16. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jérúsálẹ́mù wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jérúsálẹ́mù.’

17. “Má a ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ire kun ilú-ńlà mi ṣíbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Síónì nínú ṣíbẹ̀, yóò sì yan Jérúsálẹ́mù ṣíbẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Sekaráyà 1