Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 1:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní osù kẹ́jọ ọdún kejì Ọba Dáríúsì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekaráyà ọmọ Bérékáyà, ọmọ Ídò wòlíì pé:

2. “Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín.

3. Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn: Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí Ọ̀dọ̀ mi,’ Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

4. Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé: Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí: ‘Ẹ yípadà nísinsìnyìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí.

5. Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọn ha wà títí ayé?

6. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pà ni àṣẹ fún àwọn ìrànsẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín?“Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”

7. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sébátì, ní ọdún kejì Dáríúsì, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sekaráyà, ọmọ Berekáyà ọmọ Idò wòlíì wá, pé,

8. Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin púpa kan, òun sì dúró láàrin àwọn igi míritílì tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ si ni ẹ̀ṣin púpa, adíkálà, àti funfun gbé wà.

9. Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí Olúwa mi?”Ańgẹ́lì tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”

10. Ọkùnrin tí ó dúró láàrin àwọn igi míritílì sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”

11. Wọ́n si dá ańgẹ́lì Olúwa tí ó dúró láàrin àwọn igi mirtílì náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti ríi pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”

Ka pipe ipin Sekaráyà 1