Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanáyà 1:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. àti àwọn tí wọn ń foríbalẹ̀ tí wọnń sin ogun ọ̀run lórí òrùlé.Àwọn tí wọn ń sìn, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra,tí wọ́n sì ń fi Mólékì búra.

6. Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa;Àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.

7. Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run,nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. Olúwa ti pèṣè ẹbọ kan sílẹ̀,ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́.

8. Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa,Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọnọmọ ọba ọkùnrin,pẹ̀lú gbogboàwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ.

9. Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹgbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu ọ̀nà,tí wọ́n sì kún tẹ́ḿpìlì Olúwa wọnpẹ̀lú ìwà-ipá àti ẹ̀tàn.

10. “Ní sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,“Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà Ibodè ẹja,híhu láti ìhà kejì wá àtiariwo ńlá láti òkè kékeré wá.

11. Hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà,gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò,gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun.

12. Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jérúsálẹ́mù kiri pẹ̀lú fìtílà,èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn,tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kantí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’

13. Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógún,àti ilé wọn yóò sì run.Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́nwọn kì yóò gbé nínú ilé náà,wọn yóò gbin ọgbà àjàrà,ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtíWáìnì láti inú rẹ̀.

14. “Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkúnàwọn alágbára ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,

15. ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú,ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú,ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoroọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba,ọjọ́ kuru àti òkùnkùn biribiri,

16. ọjọ́ òpè àti ìdágìrì àti ìdágirisí àwọn ìlú olódìàti sí àwọn ìsá gíga

17. Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sóríènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú,nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa.Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí erukuàti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.

Ka pipe ipin Sefanáyà 1